Skip to content

«Ẹ jẹ ki saafu yin o dọgba, nitori pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa»

Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

«Ẹ jẹ ki saafu yin o dọgba, nitori pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa»

«سَوُّوا صُفُوفَكُمْ، فَإِنَّ تَسْوِيَةَ الصَّفِّ مِنْ تَمَامِ الصَّلَاةِ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n pa awọn olukirun láṣẹ lati maa to saafu wọn daadaa, ki apakan wọn si ma yọ siwaju ju apakeji lọ, ki wọn si ma sun sẹyin, ati pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa, ati pe wiwọ saafu si jẹ aayẹ ati adinku ninu rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ṣiṣe lofin níní akolekan gbogbo nkan ti o le mu irun pe ti yio si gbe e jina si adinku.

Ọgbọn Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nibi ikọnilẹkọọ, latari bi o ṣe so idajọ papọ mọ okunfa rẹ; ki ọgbọn ṣiṣe ofin le fojú hàn, ati ki awọn ẹmi naa le ji giri lati ṣe amulo ofin.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 145) (723).

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 324) (433).

Àlékún (6)

تيسير العلام شرح عمدة الأحكام.

للبسام (ص127).

تنبيه الأفهام شرح عمدة الأحكام.

لابن عثيمين (1/ 161).

الإفهام في شرح عمدة الأحكام.

لابن باز (ص173).