Skip to content

«Obinrin ko gbọdọ ṣe irin-ajo ti o to ọjọ meji ayaafi ki ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ o wa pẹlu rẹ

Lati ọdọ Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o jẹ ẹni ti o kopa ninu ogun mejila pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: Mo gbọ nkan mẹẹrin ni ẹnu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si jọ mi l'oju, o sọ pe:

«Obinrin ko gbọdọ ṣe irin-ajo ti o to ọjọ meji ayaafi ki ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ o wa pẹlu rẹ, ko si si aawẹ ni ọjọ meji: Itunu awẹ ati ileya, ko si tun si irun lẹyin asunbaa titi ti oorun o fi yọ, ko si si lẹyin Asri naa titi ti yio fi wọ, wọn o si tun gbọdọ di ẹru irin-ajo ayaafi lati lọ si masalasi mẹta: Masalasi abeewọ, ati masalasi aqsa, ati masalasi mi yii».

«لاَ تُسَافِرِ المَرْأَةُ مَسِيرَةَ يَوْمَيْنِ إِلَّا وَمَعَهَا زَوْجُهَا أَوْ ذُو مَحْرَمٍ، وَلاَ صَوْمَ فِي يَوْمَيْنِ: الفِطْرِ وَالأَضْحَى، وَلاَ صَلاَةَ بَعْدَ الصُّبْحِ حَتَّى تَطْلُعَ الشَّمْسُ، وَلاَ بَعْدَ العَصْرِ حَتَّى تَغْرُبَ، وَلاَ تُشَدُّ الرِّحَالُ إِلَّا إِلَى ثَلاَثَةِ مَسَاجِدَ: مَسْجِدِ الحَرَامِ، وَمَسْجِدِ الأَقْصَى، وَمَسْجِدِي هَذَا».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ kuro nibi awọn alamọri mẹẹrin kan: Alakọkọọ rẹ: Kikọ fun obinrin kuro nibi ṣiṣe irin-ajo ọjọ meji lai si pẹlu ọkọ rẹ tabi ẹnikan ninu awọn eleewọ rẹ oun naa ni ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ (ọmọbinrin naa) ni eewọ fun un ni ṣiṣe leewọ gbere ninu awọn alasunmọ-ọn, gẹgẹ bii ọmọ ati baba, ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ ọkunrin ati ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ obinrin, ati ọmọ-iya baba rẹ l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya rẹ l'ọkunrin, ati awọn to jọ bẹ́ẹ̀. Ẹlẹẹkeji rẹ: Kikọ kuro nibi gbigba aawẹ ọjọ ọdun itunu ati ọjọ ọdun ileya, ki baa ṣe pe musulumi gba mejeeji ni gbigba ti ẹ̀jẹ́, tabi aṣegbọrẹ, tabi itanran. Ẹlẹẹkẹta rẹ: Kikọ kuro nibi kiki irun naafila lẹyin irun Asri titi ti oorun o fi wọ, ati lẹyin yiyọ aarọ titi ti oorun o fi yọ. Ẹẹkẹrin rẹ: Kikọ kuro nibi ṣiṣe irin-ajo lọ si aaye kan ninu awọn aaye ati nini adisọkan ọla rẹ ati nini adisọkan pe adipele ẹsan wa nibẹ yatọ si awọn masalasi mẹta, nitori naa a ko gbọdọ di ẹru irin-ajo lọ si ibi ti o yatọ si wọn lati lọ kirun nibẹ, torí pé dajudaju adipele o ni maa ba ẹsan ayaafi ni awọn masalasi mẹta yii, masalasi abeewọ (kahbah), ati masalasi Anabi, ati masalasi aqsa.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

...:

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Aini ẹtọ ṣiṣe irin-ajo obinrin lai si eleewọ pẹlu rẹ.

Obìnrin o kii ṣe eleewọ fun obinrin ni irin-ajo; fun gbolohun rẹ ti o sọ pe: “Ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ”.

Gbogbo nkan ti wọn ba ti n pe ni irin-ajo, dajudaju wọn kọ fun obinrin ki o lọ lai si ọkọ tabi eleewọ pẹlu rẹ, ati pe hadīth yii nii ṣe pẹlu ìṣesí onibeere ati aaye rẹ.

Eleewọ obinrin ni ọkọ rẹ tabi ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ ni eewọ fun un titi láéláé latari ìbátan gẹgẹ bii baba ati ọmọ ati ọmọ-iya baba l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya l'ọkunrin, tabi ifunlọyan gẹgẹ bii baba lati ibi ifunlọyan ati ọmọ-iya baba l'ọkunrin lati ibi ifunlọyan, tabi ijẹ ana gẹgẹ bii baba ọkọ, ati pe yio jẹ musulumi ti o balaga ti o ni laakaye ti o ṣeé gbara le ti o ṣee fi ọkan tan, torí pé dajudaju nkan ti wọn gbero nibi eleewọ ni dida aabo bo obinrin ati sisọ ọ ati mimu ojú tó alamọri rẹ.

Akolekan ofin Isilaamu pẹlu ọmọbinrin ati dida aabo bo o ati sisọ ọ.

Aini alaafia kiki irun naafila lẹyin irun Al-fajri ati irun Asri, ati pe wọn yọ kuro ninu iyẹn ṣiṣe adapada awọn irun ọranyan ti o bọ, ati awọn irun ti o ni idi gẹgẹ bii tahiyyatul masjid (irun ti a maa n ki ti a ba wọ masalasi ki a to jokoo) ati eyi ti o jọ ọ.

Irun kiki jẹ eewọ ni kete lẹyin yiyọ oorun, dipo bẹ́ẹ̀ o gbọdọ gbera soke ni odiwọn ọ̀kọ̀, ni nkan ti o sunmọ iṣẹju mẹwaa titi di bii iṣẹju mẹẹdogun.

Asiko Asri gun titi di igba ti oorun o fi wọ.

O n bẹ ninu rẹ ṣiṣe ni ẹtọ didi ẹru irin-ajo lọ si awọn masalasi mẹta.

Ọla ti n bẹ fun awọn masalasi mẹtẹẹta naa lori awọn miran.

Ailẹtọọ ṣiṣe irin-ajo lati lọ bẹ saare wo koda ko jẹ saare Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe ṣiṣe abẹwo rẹ (saare Anabi) tọ fun ẹni ti o wa ni Mẹdinah, tabi ẹni ti o wa si ibẹ fun idi kan ti wọn ṣe lofin tabi ti o lẹtọọ.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (3/ 43) (1995).

Tira Sọhiihu ti Muslim (2/ 975) (827).

Àlékún (14)

فتح الباري شرح صحيح البخاري.

لابن حجر العسقلاني (4/ 75).

توضيح الأحكام مِن بلوغ المرام.

للبسام (3/ 544).

فتح ذي الجلال والإكرام شرح بلوغ المرام.

لابن عثيمين (3/ 311).

سبل السلام.

لمحمد الصنعاني (1/ 598).

مجموع فتاوى ومقالات.

لابن باز(6/ 321).

الشرح الممتع على زاد المستقنع.

لابن عثيمين (6/ 516).

شرح سنن أبي داود.

عبد المحسن العباد (65/ 8 بترقيم الشاملة آليا).