Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

90 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
«Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Mu’aadh wa lẹ́yìn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nnkan ọgun, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh ọmọ Jabal”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, o tun sọ pe: “Irẹ Mu’aadh”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, lẹẹmẹta, o sọ pe: “Ko si ẹni kankan ti o n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Allahu, ati pe Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni lododo lati inu ọkan rẹ, afi ki Ọlọhun ṣe ina leewọ fun un”, o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, njẹ mi ko nii maa sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le dunnu? O sọ pe: “Ti o ba ri bẹẹ wọn maa gbara le e”. Ni Mu’aadh wá sọ ọ́ nigba ti o fẹ ku ki o ma baa kó sínú ẹṣẹ.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
"Ikẹ Ọlọhun kó maa bá ọkunrin kan tí ó maa n ṣe ìrọ̀rùn fúnni nígbà ti ó bá tajà, ati nigba ti ó bá rajà, ati nigba ti ó bá fẹ́ gba gbèsè".
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa
“Mẹ́fà ni àwọn iṣẹ́, mẹrin si ni àwọn èèyàn, méjì maa n sọ nǹkan di dandan, ati èyí ti o ṣe pe déédéé iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan rẹ, ati eyi ti o ṣe pe iṣẹ rere kan pẹlu ẹsan mẹ́wàá ni, ati eyi ti o ṣe pe iṣẹ rere kan pẹlu ẹẹdẹgbẹrin ẹsan ni, ṣe ẹ wa ri méjì tii sọ nǹkan di dandan: Ẹni tí ó bá kú, ti ko si da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, yoo wọ alujanna, ẹni tí ó bá kú ti o si da nnkan pọ mọ Ọlọhun, yoo wọ ina, ṣe ẹ wa ri èyí ti o ṣe pe déédéé iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan rẹ: Ẹni ti o ba gbèrò dáadáa títí ti ọkàn rẹ fi mọ ọn lára, ti Ọlọhun si mọ ọn lati ọdọ rẹ, wọn maa kọ ọ silẹ fun un ni ẹsan kan, ẹni tí ó bá ṣe aburu kan, wọn maa kọ ọ silẹ fun un ni aburu kan, ẹni tí o ba ṣe dáadáa kan, o maa gba ẹsan mẹ́wàá irú rẹ, ẹni tí ó bá na owó si oju-ọna Ọlọhun, dáadáa kan maa wa pẹlu ẹsan ẹẹdẹgbẹrin, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn, o n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun maa gbòòrò arisiki rẹ ni ayé ṣùgbọ́n ti o maa ri ifunpinpin ni alukiyaamọ, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun ko nii gbòòrò arisiki fun ni ayé, ṣùgbọ́n o maa ri igbalaaye ni alukiyaamọ, o tun bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun ko nii gbòòrò arisiki fun ni ayé ati alukiyaamọ, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun maa gbòòrò arisiki rẹ ni ayé ati alukiyaamọ”.
O daa Ahmad ni o gba a wa
“Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Ọkùnrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pé: Nǹkan ọ̀gùn mi ti kú, fun mi ni nǹkan ti maa gùn, ni o wa sọ pé: “Mi o ni”, arákùnrin kan wa sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, maa júwe fun un ẹni tí ó maa fun un ni nǹkan ti o maa gùn, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Ẹni ti o ba ṣe amọ̀nà lọ sibi oore, o maa ní irú ẹsan ẹni tí ó bá ṣe e”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
“Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
"Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ", wọn sọ pé: Tani? Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ẹni ti o ba obi rẹ mejeeji nigba ogbo, ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji ti ko wa wọ alujanna".
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa