Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

64 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
“Dájúdájú Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ẹrú ti o jẹ olupaya ọlọ́rọ̀ ti o pamọ́”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n rin loju ọna Makkah, ni o ba kọjá nibi oke kan ti wọn n pe e ni Jumdaan, o sọ pe: "Ẹ maa rin lọ, Jumdaan nìyí, àwọn MUFARRIDUUN ti ṣíwájú" wọn sọ pe: Awọn wo ni MUFARRIDUUN irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: Awọn ni àwọn oluranti Ọlọhun lọkunrin lọpọlọpọ ati awọn oluranti Ọlọhun lobinrin".
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun àbúrò bàbá rẹ̀ pé: “Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde”, o sọ pe: Ti kii ba ṣe pe àwọn Quraysh maa bu mi ni, ti wọn maa sọ pé: Ìbẹ̀rù ni o mu un sọ ọ́, mi o ba fi dùn ọ́ nínú. Ni Ọlọhun wa sọ aaya yii kalẹ̀: {Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́} [Al-Qasas: 56].
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Ẹ ko gbọdọ wọ aṣọ alaari, ẹ ko si gbọdọ mu ninu igba wura ati fadaka, ẹ ko si gbọdọ jẹ ninu abọ tí wọ́n fi mejeeji ṣe, nitori pe awọn (keferi) ni wọn ni i laye, tiwa (musulumi) si ni ni ọjọ ikẹyin.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
“Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii ṣàánú ẹni tí kii ba ṣàánú àwọn èèyàn”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
“Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
“Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbọ ti arákùnrin kan n ṣe wáàsí fun ọmọ-iya rẹ nipa ìtìjú, o wa sọ pé: “Itiju wa ninu igbagbọ”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni