Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

5 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
“Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti síwájú”
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa
Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)».
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa
Dajudaju Ummu Salamah dárúkọ ṣọọṣi kan ti o ri ni ilẹ̀ Habasha fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn n pe e ni Maariyah, o wa sọ nnkan ti o ri nibẹ fun un ninu awọn aworan, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ, wọn yoo si ya awọn aworan yẹn síbẹ̀, awọn wọnyẹn ni awọn ti wọn buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun".
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Dajudaju mo jẹ ẹni ti maa n ri ẹjẹ awaada ti mii si ki n si ni imọra, njẹ mo le fi irun silẹ? Ni o wa sọ pe: «Rara, dajudaju ẹjẹ iṣan niyẹn, ṣugbọn maa fi irun silẹ ni odiwọn awọn ọjọ ti o fi maa n ri ẹjẹ nkan oṣu, lẹyin naa ki o wa wẹ ki o si kirun».
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun rẹ, titi ti yio fi ro ni ẹmi rẹ pe o ti kan awọ isalẹ irun rẹ, yio wa da omi si ara ni ẹẹmẹta, lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku, ni o wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ papọ ninu igba kan náà, ti a si jọ maa n fi ọwọ bu omi papọ ninu rẹ.
O ni alaafia Bukhaariy lọ gba a wa