Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

5 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
«Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ, maa ṣe ojukokoro lori nkan ti yio ṣe ọ ni anfaani, ki o si tun wa iranlọwọ pẹlu Ọlọhun, má si kagara, ati pe ti nkankan ba ṣẹlẹ si ọ, o ko wa gbọdọ sọ pe kani mo ṣe báyìí nkan báyìí báyìí ni ko ba jẹ, ṣugbọn sọ pe kọdarullāh wa maa sha'a fa‘al "akọsilẹ Ọlọhun ni, nkan ti O si fẹ ni O ṣe", tori pe (lao) "kani" o maa ṣina iṣẹ satani»
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
“Ti Mùsùlùmí méjì ba pàdé ara wọn pẹ̀lú idà, ati ẹni ti o pa eeyan ati ẹni tí wọ́n pa, wọn jọ maa wọ iná ni”, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a gbọ ti ẹni tí o pa èèyàn, ẹni tí wọ́n pa wa nkọ? O sọ pé: “Oun naa fẹ́ pa ẹni keji rẹ ni”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
“Ọlọhun, Oníbùkún ti O ga jùlọ, sọ pe: Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
“Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
"Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun".
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni