Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

104 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́

Olùgbàsọ

Fi gbogbo olùgbàsọ hàn (53)
Arakunrin kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ni nnkan meji naa ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ku ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna, ẹni ti o ba si ku ti o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina".
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
"Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn, ati pe ẹni ti o ba pepe lọ si ibi anu, iru awọn ẹṣẹ ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹṣẹ, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn".
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
"Awọn alakatakiti ti parun " ó sọ bẹẹ ni ẹẹmẹta.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
“Dajudaju Ọlọhun ko nii ṣe abosi olugbagbọ kan ni ti daadaa ti o ba ṣe, wọn yoo fun un ni ẹsan rẹ ni aye, wọn si tun maa san an ni ẹsan pẹlu rẹ ni ọrun, sugbọn alaigbagbọ wọn maa fun un ni oúnjẹ jẹ pẹlu awọn daadaa nnkan ti o ba ṣe ni iṣẹ́ nitori Ọlọhun ni aye, ti o ba ti wa de ọrun, daadaa kan ko nii maa jẹ tirẹ ti wọn maa san an lẹsan pẹlu rẹ”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
A jẹ lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, mẹ́sàn-án tabi mẹjọ tabi meje, o wa sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" A si ṣẹṣẹ ṣe adehun kan tan ni, a sọ pe: A ti ṣe adehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, lẹyin naa, o sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" A sọ pé: Dajudaju a ti ṣadehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, leyin naa, o sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" O sọ pe: A wa tẹ awọn ọwọ wa, a si sọ pé: A ti ṣadehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan" dajudaju mo ti ri awọn kan ninu awọn ẹni yẹn, ti ọrẹ ẹnikan ninu wọn ba jabọ, ko nii ni ki ẹni kankan o ba oun mu un.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Mo lọ pẹlu awọn ikọ bani Āmir si ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni a wa sọ pe: Iwọ ni olowo wa, ni o wa sọ pe: "Allāhu ni Olowo", a sọ pe: ati ọlọlajulọ inu wa, ati ọlọrọ julọ inu wa, ni o wa sọ pe: «Ẹ maa sọ awọn ọrọ yin, tabi apakan awọn ọrọ yin, ẹ ma jẹ ki esu o lo yin (ki o gbe yin kọja aala)».
O ni alaafia Baba Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
“Ẹni ti o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din in ku tabi ki o ni ki o ma san an mọ́, Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Ìtẹ́-ọlá Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde, ni ọjọ́ ti ko nii si ibòji kankan àyàfi ibòji Rẹ̀”.
O ni alaafia Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
“Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”.
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa