Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

95 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
«Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ».
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
Arakunrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju ọ̀kan ninu wa n ri ninu ẹ̀mí rẹ- o n pẹ́ nǹkan náà sọ pẹ̀lú itọka- o nífẹ̀ẹ́ si ki oun jẹ eeru ju ki o sọ ọ lọ, o wa sọ pe: “ Ọlọhun tobi Ọlọhun tobi, ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O da ete rẹ pada si royiroyi".
O ni alaafia Baba Daud ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú tira al-Kubrọ
Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ" mo sọ pe: Dajudaju ìyẹn tobi, mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o pa ọmọ rẹ; ti o n bẹru ki o maa jẹun pẹlu rẹ" mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣìná".
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
"Ẹ tẹti ẹ gbọ, o ṣee ṣe ki arakunrin kan, ki hadisi nipa mi de etigbọọ rẹ ti o si rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ki o wa maa sọ pe: Iwe Ọlọhun n bẹ laaarin wa ati yin, nǹkan ti a ba ri nibẹ ni ẹtọ a maa ṣe e ni ẹtọ, nnkan ti a ba si ri nibẹ ni eewọ a maa ṣe e ni eewọ. Ati pe dajudaju nnkan ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣe ni eewọ da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ".
O ni alaafia Baba Daud ati Tirmisiy ati Ọmọ Maajah ni wọn gba a wa
“Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà, Ọlọhun ti ṣẹbi lé awọn ijọ kan tí wọ́n sọ saare awọn Anabi wọn di mọṣalaṣi”.
O ni alaafia Ahmad ni o gba a wa
Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nigba ti o jade lọ si Hunayn o rekọja nibi igi kan ti o jẹ ti awọn ọṣẹbọ ti wọn n pe e ni: Dhaatu anwaat ti wọn maa n fi awọn nkan ija wọn kọ ọ, ni wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ṣe dhaatu anwaat fun wa gẹgẹ bi wọn ṣe ni dhaatu anwaat, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Mimọ fun Ọlọhun! Eleyii da gẹgẹ bi nkan ti awọn ijọ Musa sọ {ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan} [Al-'A‘roof: 138] mo wa fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹ o maa tẹle ilana awọn ti wọn ṣaaju yin».
O ni alaafia Tirmisiy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ".
O ni alaafia pẹ̀lú akojọpọ àwọn ọ̀nà rẹ ti o gbà wa Baba Daud ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú tira al-Kubrọ, ati Ahmad
“Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, iná ayé gan ti tó. O sọ pe: “Ina Jahannama ju ti aye lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, gbígbóná ọkọọkan ninu ẹ da gẹgẹ bii gbígbóná iná ayé”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni