Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

70 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
“Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ, ìyẹn ni igba ti: (ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà)) Al-An’am, Ayah 158. Alukiyaamọ maa tó, ti ọkùnrin meji si ti tẹ aṣọ silẹ láàrin ara wọn, wọn ko si nii lee ta ọjà fun ara wọn bẹẹ ni wo ko si nii lee ka a padà, alukiyaamọ maa tó, ti èèyàn si ti bu wàrà ràkúnmí rẹ lọ ti ko si nii le mu u, alukiyaamọ maa tó, ti ó sì ti tún àmù omi rẹ ṣe, ko si nii le fun awọn ẹran ọ̀sìn rẹ mu nínú ẹ, alukiyaamọ maa tó, ti ẹnìkan nínú yin si ti gbe oúnjẹ rẹ sí ẹnu, ko si nii lee jẹ ẹ”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Nigba ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pọka iku, o bẹ̀rẹ̀ si nii fi aṣọ nu oju rẹ, ti o ba ti wa di pe ko le mí mọ́ daadaa, o maa ka a kuro loju rẹ, o wa sọ bi o ṣe wa bẹẹ pe: “Egbe Ọlọhun ko lọ maa ba awọn Juu ati Nasara, ti wọn mu awọn saare awọn Anabi wọn ni mọsalasi” ti o n ṣe ikilọ kuro nibi nnkan ti wọn ṣe.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti mi, mo si ti bo apoti iko-nnkan-si ti o jẹ temi pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan n bẹ nibẹ, nigba ti o wa ri i, o fa a ya ti oju rẹ si pọn, o wa sọ pe: "Irẹ 'Aaisha, Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun" 'Aaisha sọ pe: "A si ge e, a si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì".
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
“Wọn maa mu ikú wá ni ìrísí àgbò ti o ni dúdú ati funfun lára, olupepe kan maa pè pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna, wọn maa garùn wọn si maa wò, yoo wa sọ pé: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, lẹyin naa o maa pe pe: Ẹyin ọmọ iná, wọ́n maa garùn wọ́n sì maa wò, o maa waa sọ pe: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, wọn maa du u, lẹyin naa o maa sọ pé: Ẹyin ọmọ alujanna, gbére, ko si ikú mọ, ẹyin ọmọ iná, gbére, ko si ikú mọ, lẹyin naa ni o ka: {Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná} [Maryam: 39], àwọn wọ̀nyí wa ninu igbagbera ni àwọn ará ayé, {wọn kò sì gbàgbọ́} [Maryam: 30]”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún, o lo ọdún mẹtala ni ìlú Makkah, lẹyin naa ni wọn pa a láṣẹ ki o ṣe hijra, o wa ṣe hijra lọ sí ìlú Madina, o wa lo ọdún mẹ́wàá nibẹ, lẹyin naa ni o wa kú (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh, njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ, ati nnkan ti o jẹ iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun?”, mo sọ pe: Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ ẹni ti ko ba da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ”, mo sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ṣe ki n maa fun awọn eniyan ni iro idunnu nipa rẹ? O sọ pe: “Rara, ma fun wọn ni iro ìdùnnú, ki wọn ma baa gbára lé e”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa fun wa ni Hudaibiyah lẹ́yìn ojo ti o rọ̀ ni òru, lẹ́yìn tí ó kírun tán, o kọju si awọn eniyan, o sọ pe: “Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ, ẹni tí ó bá sọ pé: Wọ́n rọ òjò fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ, ìyẹn ni ẹni tí ó gbagbọ ninu Mi ti o si ṣe aigbagbọ si ìràwọ̀, ṣugbọn ẹni tí o ba sọ pe: Pẹ̀lú ìràwọ̀ bayii bayii, ìyẹn ni ẹni tí o ṣe aigbagbọ ninu Mi, ti o wa ni igbagbọ ninu ìràwọ̀”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Arakunrin kan sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ wọn maa ba wa wí nípa nnkan ti a ṣe ni asiko aimọkan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni