Skip to content
342 Hadith

Ìwé-ìmọ̀ Àwọn Hadith Ànábì

Ṣàtò àwọn èsì

48 nínú káàdì 342

Pa àwọn àṣàyàn rẹ́
Mo ha rakah mẹwaa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Rakah meji ṣíwájú irun Zuhr, ati rakah meji lẹyin rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Magrib ni ile rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Ishai ni ile rẹ, ati rakah meji ṣíwájú irun Subhi; o jẹ asiko kan ti wọn ko ki n wọle ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibẹ, Hafsoh sọ fun mi pe ti oluperun ba ti pe irun ti alufajari ba si ti yọ, o maa ki rakah meji, o wa ninu ẹgbawa kan pé: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ki rakah meji lẹyin irun jimọh.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni i pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹgbawa rẹ
“Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”.
O ni alaafia Baba Daud ni o gba a wa
«Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi ki o yaa sọ pe: Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika, ti o ba si tun jade ki o sọ pe: Allāhummo inni as’aluka min fadlika».
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa
“Ẹni ti o ba gbagbe irun kan ki o yaa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un afi ìyẹn: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14)”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Dajudaju Uthman ọmọ ‘Affan fẹ kọ mọsalasi ni awọn eniyan ba korira ìyẹn, wọn nífẹ̀ẹ́ si ki wọn fi i kalẹ bi o ṣe wa, o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
«Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje: Lori iwaju ori, o si na ọwọ rẹ si imu rẹ, ati ọwọ mejeeji, ati orunkun mejeeji, ati awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji, ati pe ki a ma ka awọn aṣọ ati irun».
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Dajudaju awọn ọkunrin kan wa ba Sahl ọmọ Sahd As-Saa’idiyy, wọn ṣe iyemeji nipa minbari latara nnkan wo ni igi rẹ ti wa, ni wọn wa bi i leere nipa ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mo mọ latara nnkan ti o ti wa, dajudaju mo ri i ni ọjọ akọkọ ti wọn gbe e kalẹ, ati ọjọ akọkọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jokoo sori rẹ, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ranṣẹ si lagbaja- obinrin kan ninu awọn Ansar ti Sahl si ti dárúkọ rẹ-: “Pa ọmọ-ọdọ rẹ ti o jẹ kafinta láṣẹ ki o kan awọn igi kan fun mi ti maa maa jokoo le wọn lori ti mọ ba fẹ ba awọn eniyan sọ̀rọ̀”, ni o wa pa a láṣẹ o si ṣe e latara igi TỌRFAAHU ti o maa n wa nínú igbó, lẹyin naa o gbe e wa, ni o wa ranṣẹ si ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa ni ki wọn gbe wọn kalẹ sí ibì kan, lẹyin naa ni mo ri ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o kirun lori rẹ, ti o si kabara nigba ti o wa lori rẹ, lẹyin naa o rukuu ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o sọkalẹ ti o n fi ẹyin rìn, ni o wa forikanlẹ sibi isalẹ minbari, lẹyin naa o ṣẹri pada, nigba ti o pari o doju kọ awọn eniyan, ni o wa sọ pe: “Ẹyin ènìyàn, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le tẹle mi ki ẹ si le kọ́ irun kiki mi”.
O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Ibnu Zubayr jẹ ẹniti o maa n sọ ni ẹyin ìrun kọọkan nigba ti o ba salamọ pe: “Laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharīka lahu, lahul mulku wa lahul hamdu wa huwa ala kulli shay’in qodīr, laa haola walā quwwata illā biLlāh, lā ilāha illā Allāhu, wa lā na‘budu illā iyyāhu, lahu ni‘matu wa lahul fadlu wa lahuu thanāhul hasan, lā ilāha illā Allāhu mukhlisiina lahuu dīna wa lao karihal kāfirūna”, o wa sọ pe: «Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan».
O ni alaafia Muslim ni ọ gba a wa