Skip to content

“Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”.

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

“Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”.

«مَنْ يَقُمْ لَيْلَةَ الْقَدْرِ إِيمَانًا وَاحْتِسَابًا غُفِرَ لَهُ مَا تَقَدَّمَ مِنْ ذَنْبِهِ»

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
O ni alaafia
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa nipa ọla idide ni oru Laelatul Kọdri ti o maa n wa ni mẹ́wàá ikẹyin ninu oṣù Ramadan, ati pe ẹni ti o ba gbìyànjú ninu ẹ pẹ̀lú ìrun ati adua ati kika Kuraani ati iranti, ni ẹni tí o gba a gbọ́ ati ọla ti n bẹ fun un, ti o si n reti ẹsan Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, ti kii ṣe ti ṣekarimi tabi ṣekagbọmi, wọn maa fi orí àwọn ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in.

Ìtumọ̀ àwọn gbólóhùn

إيمانًا: تصديقًا بالله وبوعده.

احتسابًا: طلبًا للثواب والأجر من الله عز وجل.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

Ọla ti n bẹ fun oru Laelatul Kọdri, ati ṣisẹnilojukokoro lori idide ninu ẹ.

Wọn ko nii gba àwọn iṣẹ olóore ayafi pẹ̀lú àníyàn òdodo.

Ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ̀; tori pe ẹni tí ó bá dide ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in.

Àwọn ìwé ìwádìí

Tira Sọhiihu ti Bukhaariy (1/ 16) (35).

Tira Sọhiihu ti Muslim (1/ 523) (760).

(2/ 846).

Àlékún (10)

كنوز رياض الصالحين.

لمجموعة من الباحثين (14/ 435).

بهجة الناظرين.

لسليم الهلالي (2/ 337).

نزهة المتقين.

شرح النووي على مسلم (6/ 40).

شرح رياض الصالحين.

لابن عثيمين (5/ 220).

شرح صحيح البخاري.

لابن بطال (4/ 21).